Psalms 10:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn ìwọ Ọlọrun rí gbogbo nǹkan, nítòótọ́, o kíyèsí ìṣòro ati ìyà, kí o baà lè fi ọwọ́ ara rẹ gbẹ̀san; nítorí ìwọ ni àwọn aláìṣẹ̀ gbẹ́kẹ̀lé, ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìníbaba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ ti ri i; nitori iwọ nwò ìwa-ìka ati iwọsi, lati fi ọ̀ran na le ọwọ rẹ; talaka fi ara rẹ̀ le ọ lọwọ; iwọ li oluranlọwọ alaini-baba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni o ri wàhálà àti ìrora; Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ Rẹ. talákà fara Rẹ̀ jin fún ọ; Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba.