Psalms 101:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo múra láti hu ìwà pípé pẹlu ọgbọ́n; nígbà wo ni o óo wá sọ́dọ̀ mi? N óo máa fi tọkàntọkàn rin ìrìn pípé ninu ilé mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o ma rìn ìrin mi pẹlu ọgbọ́n li ọ̀na pipé. Nigbawo ni iwọ o tọ̀ mi wá! emi o ma rìn ninu ile mi pẹlu aiya pipé.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò máa rin ìrìn mi pẹ̀lú ọgbọ́n láìlẹ́sẹ̀, ìgbà wo ni ìwọ yóò wá sí ọ̀dọ̀ mi? Èmi yóò máa rìn ní ilé mi pẹ̀lú àyà pípé.