Psalms 106:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí n lè rí ire àwọn àyànfẹ́ rẹ kí n lè ní ìpín ninu ayọ̀ àwọn eniyan rẹ, kí n sì lè máa ṣògo pẹlu àwọn tí ó jẹ́ eniyan ìní rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki emi ki o le ri ire awọn ayanfẹ rẹ, ki emi ki o le yọ̀ ninu ayọ̀ orilẹ-ède rẹ, ki emi ki o le ma ṣogo pẹlu awọn enia ilẹ-ini rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn ìní Rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo.