Psalms 106:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn baba ńlá wa wà ní Ijipti, wọn kò náání iṣẹ́ ìyanu rẹ, wọn kò sì ranti bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ti pọ̀ tó. Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo lẹ́bàá òkun pupa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iṣẹ iyanu rẹ kò yé awọn baba wa ni Egipti; nwọn kò ranti ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ; ṣugbọn nwọn ṣọ̀tẹ si ọ nibi okun, ani nibi Okun pupa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn baba wa wà ní Éjíbítì iṣẹ́ ìyanu Rẹ kò yé wọn wọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú Rẹ gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe sọ̀tẹ̀ sí ọ níbi òkun, àní nibi òkun pupa