Psalms 12:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA wí pé, “Nítorí ìnira àwọn aláìṣẹ̀, ati nítorí ìkérora àwọn tí à ń pọ́n lójú, n óo dìde nisinsinyii, n óo sì dáàbò bò wọ́n bí ọkàn wọn ti ń fẹ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori inira awọn talaka, nitori imi-ẹ̀dun awọn alaini, Oluwa wipe, nigbayi li emi o dide; emi o si yọ ọ si ibi ailewu kuro lọwọ ẹniti nfẹ̀ si i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí ìnilára àwọn aláìlágbára àti ìkéróra àwọn aláìní, Èmi yóò dìde nísinsin yìí” ni OLÚWA wí. “Èmi yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe àrankàn wọn”