Psalms 127:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Asán ni kí á jí ní òwúrọ̀ kutukutu, kí á tún pẹ́ títí kí á tó sùn. Asán ni kí á máa fi làálàá wá oúnjẹ; nítorí pé OLUWA a máa fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ ní oorun sùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Asan ni fun ẹnyin ti ẹ dide ni kutukutu lati pẹ iṣiwọ, lati jẹ onjẹ lãlã: bẹ̃li o nfi ire fun olufẹ rẹ̀ loju orun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù lati pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ́ làálàá; bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ire fún olùfẹ́ Rẹ̀ lójú ọ̀run.