Psalms 17:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA, fi ọwọ́ ara rẹ gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan wọnyi; àwọn tí ìpín wọn jẹ́ ohun ti ayé yìí, fi ohun rere jíǹkí àwọn ẹni tí o pamọ́; jẹ́ kí àwọn ọmọ jẹ àjẹyó; sì jẹ́ kí àwọn ọmọ ọmọ wọn rí ogún wọn jẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lọwọ awọn enia nipa ọwọ rẹ, Oluwa, lọwọ awọn enia aiye, ti nwọn ni ipin wọn li aiye yi, ati ikùn ẹniti iwọ fi ohun iṣura rẹ ìkọkọ kún: awọn ọmọ wọn pọ̀n nwọn a si fi iyokù ini wọn silẹ fun awọn ọmọ-ọwọ́ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA, nípa ọwọ́ Rẹ gbà mí kúrò lọ́wọ́ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀, kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ayé yìí, tí èrè wọn wà nínú ayé yìí; Ìwọ ń pa ebi àwọn tí ìwọ fẹ́ràn lẹ́nu mọ́; àwọn ọmọ wọn sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, wọ́n sì kó ọrọ̀ jọ fún àwọn ọmọ wọn.