Psalms 19:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
sibẹ ìró wọn la gbogbo ayé já, ọ̀rọ̀ wọn sì dé òpin ayé. Ó pàgọ́ fún oòrùn lójú ọ̀run,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iró wọn la gbogbo aiye ja, ati ọ̀rọ wọn de opin aiye: ninu wọn li o gbe pagọ fun õrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayé ọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé, ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run.