Psalms 2:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ júbà ọmọ náà, kí ó má baà bínú, kí ó má baà pa yín run lójijì; nítorí a máa yára bínú. Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó wá ààbò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Fi ẹnu kò Ọmọ na lẹnu, ki o máṣe binu, ẹnyin a si ṣegbe li ọ̀na na, bi inu rẹ̀ ba ru diẹ kiun. Ibukún ni fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹ wọn le e.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú kí ó má ba à payin run ní ọ̀nà yin, nítorí ìbínú Rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan. Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi i ṣe ibi ìsádi wọn.