Psalms 22:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn agbéraga láyé ni yóo wólẹ̀ níwájú rẹ̀; gbogbo ẹni tí yóo fi ilẹ̀ bora bí aṣọ ni yóo wólẹ̀ níwájú rẹ̀, àní, gbogbo àwọn tí kò lè dá sọ ara wọn di alààyè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn ti o sanra li aiye yio ma jẹ, nwọn o si ma wolẹ-sìn: gbogbo awọn ti nsọkalẹ lọ sinu erupẹ yio tẹriba niwaju rẹ̀, ati ẹniti kò le pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ li ãye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àṣè, wọn yóò sì sìn; gbogbo àwọn tí ó wọ inú ilẹ̀ lọ yóò kúnlẹ̀ ní iwájúu Rẹ̀ àti ẹni ti kò le pa ọkàn ara Rẹ̀ mọ́ ni ààyè.