Psalms 23:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àní, bí mo tilẹ̀ ń rìn ninu òkùnkùn létí bèbè ikú, n kò ní bẹ̀rù ibi kankan; nítorí tí o wà pẹlu mi; ọ̀gọ rẹ ati ọ̀pá rẹ ń fi mí lọ́kàn balẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitõtọ, bi mo tilẹ nrìn larin afonifoji ojiji ikú, emi kì yio bẹ̀ru ibi kan; nitori ti Iwọ pẹlu mi; ọgọ rẹ ati ọpá rẹ nwọn ntù mi ninu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí mo tílẹ̀ ń rìn Láàrin àfonífojì òjiji ikú, èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan; nítorí ìwọ wà pẹ̀lú ù mi; ọ̀gọ Rẹ àti ọ̀pá à Rẹ wọ́n ń tù mi nínú.