Psalms 31:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mò ń gbọ́ tí ọ̀pọ̀ eniyan ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, bí wọ́n ti ń gbìmọ̀ pọ̀ nípa mi, tí wọ́n sì ń pète ati pa mí; wọ́n ń ṣẹ̀rù bà mí lọ́tùn-ún lósì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ti emi ti ngbọ́ ẹ̀gan ọ̀pọ enia: ẹ̀ru wà niha gbogbo: nigbati nwọn ngbimọ pọ̀ si mi, nwọn gbiro ati gbà ẹmi mi kuro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpayà tí ó yí mi ká; tí wọn gbìmọ̀ pọ̀ sí mi, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi láti gba ẹ̀mi mi.