Psalms 31:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Má jẹ́ kí ojú tì mí, OLUWA, nítorí ìwọ ni mò ń ké pè. Jẹ́ kí ojú ti àwọn eniyan burúkú; jẹ́ kí ẹnu wọn wọ wòwò títí wọ ibojì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Máṣe jẹ ki oju ki o tì mi, Oluwa; nitori ti emi nkepè ọ; enia buburu ni ki oju ki o tì, awọn ni ki a mu dakẹ ni isa-okú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Má ṣe jẹ́ kí á fi mí sínú ìtijú, OLÚWA; nítorí pé mo ké pè ọ́; jẹ́ kí ojú kí ó ti ènìyàn búburú; jẹ́ kí wọ́n lọ pẹ̀lú ìdààmú sí isà òkú.