Psalms 31:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀rù bà mí, mo sì sọ pé, “A lé mi jìnnà kúrò ní iwájú rẹ.” Ṣugbọn o gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ti mo ti wi ni ikanju mi pe, A ke mi kuro niwaju rẹ: ṣugbọn iwọ gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi nigbati mo kepè ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmí ti sọ nínú ìdágìrì mi, “A gé mi kúrò ní ojú Rẹ!” Ṣíbẹ̀ ìwọ́ ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.