Psalms 32:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, kí gbogbo olódodo máa gbadura sí ọ; ní àkókò tí ìpọ́njú bá ń yí lura wọn bí ìṣàn omi ńlá, kò ní dé ọ̀dọ̀ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori eyi li olukulùku ẹni ìwa-bi-ọlọrun yio ma gbadura si ọ ni igba ti a le ri ọ: nitõtọ ninu iṣan-omi nla, nwọn kì yio sunmọ ọdọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ ní ìgbà tí a le ri ọ; nitòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè, wọn kì yóò le dé ọ̀dọ̀ Rẹ̀.