Psalms 37:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA; fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé e. Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí ẹni tí nǹkan ń dára fún; tabi nítorí ẹni tí ń gbèrò ibi, tí ó sì ń ṣe é.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ simi ninu Oluwa, ki o si fi sũru duro dè e; máṣe ikanra nitori ẹniti o nri rere li ọ̀na rẹ̀, nitori ọkunrin na ti o nmu èro buburu ṣẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ dákẹ́ jẹ́ ẹ́ níwájú OLÚWA, kí o sì fi sùúrù dúró dè é; má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn, nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ.