Psalms 39:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“OLUWA, gbọ́ adura mi, tẹ́tí sí igbe mi, má dágunlá sí ẹkún mi, nítorí pé àlejò rẹ, tí ń rékọjá lọ ni mo jẹ́; àjèjì sì ni mí, bíi gbogbo àwọn baba mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa, gbọ́ adura mi, ki o si fi eti si ẹkún mi, ki o máṣe pa ẹnu rẹ mọ́ si omije mi: nitori alejo li emi lọdọ rẹ, ati atipo, bi gbogbo awọn baba mi ti ri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Gbọ́ àdúrà mi, OLÚWA, kí o sì fetí sí igbe mi; kí o má ṣe di etí Rẹ sí ẹkún mi nítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ Rẹ àti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí.