Psalms 41:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó bá wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn, OLUWA yóo fún un lókun; ní àkókò àìlera OLUWA yóo wo gbogbo àrùn rẹ̀ sàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa yio gbà a ni iyanju lori ẹní àrun: iwọ o tẹ ẹní rẹ̀ gbogbo ni ibulẹ arun rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA yóò gbà á lórí àkéte àìsàn Rẹ̀ yóò sì mú-un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn Rẹ̀.