Psalms 41:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Tí ọ̀kan bá wá bẹ̀ mí wò, ọ̀rọ̀ tí kò lórí, tí kò nídìí ni yóo máa sọ; bẹ́ẹ̀ ni ninu ọkàn rẹ̀, èrò ibi ni yóo máa gbà. Nígbà tí ó bá jáde, yóo máa rò mí kiri.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o ba si wá wò mi, on a ma sọ̀rọ ẹ̀tan: aiya rẹ̀ kó ẹ̀ṣẹ jọ si ara rẹ̀; nigbati o ba jade lọ, a ma wi i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà kígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí, wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà Rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara Rẹ̀; nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kalẹ̀.