Psalms 42:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn nǹkan wọnyi ni mò ń ranti, bí mo ti ń tú ẹ̀dùn ọkàn mi jáde: bí mo ṣe máa ń bá ogunlọ́gọ̀ eniyan rìn, tí mò ń ṣáájú wọn, bí a bá ti ń rìn lọ́wọ̀ọ̀wọ́ lọ sí ilé Ọlọrun; pẹlu ìhó ayọ̀ ati orin ọpẹ́, láàrin ogunlọ́gọ̀ eniyan tí ń ṣe àjọ̀dún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati mo ba ranti nkan wọnyi, emi tú ọkàn mi jade ninu mi: emi ti ba ọ̀pọ ijọ enia lọ, emi ba wọn lọ si ile Ọlọrun, pẹlu ohùn ayọ̀ on iyìn, pẹlu ọ̀pọ enia ti npa ọjọ mimọ́ mọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí mo bá rántí nǹkan yìí, èmi tú ọkàn mi jáde nínú mi: èmi ti bá ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn lọ, èmi bá wọn lọ sí ilé Ọlọ́run pẹ̀lú ohùn ayọ̀ àti ìyìn, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pa ọjọ́ mímọ́ mọ́.