Psalms 44:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé kì í ṣe idà wọn ni wọ́n fi gba ilẹ̀ náà, kì í ṣe agbára wọn ni wọ́n fi ṣẹgun; agbára rẹ ni; àní, agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ati ojurere rẹ; nítorí pé inú rẹ dùn sí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti nwọn kò ni ilẹ na nipa idà ara wọn, bẹ̃ni kì iṣe apá wọn li o gbà wọn; bikoṣe ọwọ ọtún rẹ ati apá rẹ, ati imọlẹ oju rẹ, nitoriti iwọ ni ifẹ rere si wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọn gba ilẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kì í se apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò se; ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ àti, apá Rẹ̀; àti ìmọ́lẹ̀ ojú Rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn.