Psalms 5:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn jẹ́ kí inú gbogbo àwọn tí ó sá di ọ́ ó dùn, kí wọn ó máa kọrin ayọ̀ títí lae. Dáàbò bò wọ́n, kí àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ sì máa yọ̀ ninu rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni gbogbo awọn ti ngbẹkẹle ọ yio yọ̀; lai nwọn o ma ho fun ayọ̀, nitoriti iwọ dabobo wọn: ati awọn ti o fẹ orukọ rẹ pẹlu yio ma yọ̀ ninu rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀; jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí. Tan ààbò Rẹ sórí wọn, àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ Rẹ yóò máa yọ̀ nínú Rẹ.