Psalms 53:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ wò wọ́n, bí wọ́n ṣe wà ninu ẹ̀rù ńlá, ẹ̀rù tí kò tíì sí irú rẹ̀ rí! Nítorí Ọlọrun yóo fọ́n egungun àwọn ọ̀tá rẹ̀ ká; ojú óo tì wọ́n, nítorí Ọlọrun ti kọ̀ wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nibẹ ni nwọn gbe wà ni ibẹ̀ru nla nibiti ẹ̀ru kò gbe si: nitori Ọlọrun ti fún egungun awọn ti o dótì ọ ka: iwọ ti dojutì wọn, nitori Ọlọrun ti kẹgàn wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Níbẹ̀ ni ìwọ gbé wà ní ìbẹ̀rù ńlá níbì tí ẹ̀rù kò gbé sí nítorí Ọlọ́rún tí fọ́n egungun àwọn tí ó dótì ọ́ ká; ìwọ tí dójú tì wọ́n, nítorí Ọlọ́run ti kẹ́gàn wọn.