Psalms 55:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ìwọ, Ọlọrun, o óo sọ àwọn apani ati àwọn alárèékérekè, sinu kòtò ìparun; wọn kò ní lo ìdajì ọjọ́ ayé wọn. Ṣugbọn èmi óo gbẹ́kẹ̀lé ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn iwọ, Ọlọrun, ni yio mu wọn sọkalẹ lọ si iho iparun: awọn enia ẹ̀jẹ ati enia ẹ̀tan kì yio pe àbọ ọjọ wọn; ṣugbọn emi o gbẹkẹle ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni yóò mu àwọn ọ̀tá mi wá sí ihò ìparun; Àwọn ẹni tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti ẹni ẹ̀tàn kì yóò gbé ààbọ̀ ọjọ́ wọn. Ṣùgbọ́n fún èmi, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ.