Psalms 56:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
A óo lé àwọn ọ̀tá mi pada ní ọjọ́ tí mo bá ké pè ọ́. Mo mọ̀ dájú pé Ọlọrun ń bẹ fún mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ ti mo ba kigbe, nigbana li awọn ọta mi yio pẹhinda: eyi li emi mọ̀: nitoripe Ọlọrun wà fun mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóò pẹ̀yìndà nígbà tí mo bá pè fún ìrànlọ́wọ́ nípa èyí ní mo mọ̀ pé Ọlọ́run ń bẹ fún mi