Psalms 57:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ààrin àwọn kinniun ni mo dùbúlẹ̀ sí, àwọn tí ń jẹ eniyan ní ìjẹ ìwọ̀ra; eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ ati ọfà, ahọ́n wọn sì dàbí idà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkàn mi wà lãrin awọn kiniun: emi tilẹ dubulẹ lãrin awọn ti o gbiná, eyinì ni awọn ọmọ enia, ehín ẹniti iṣe ọ̀kọ ati ọfa, ati ahọn wọn, idà mimú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo wà ní àárin àwọn kìnnìún; mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú àwọn ènìyàn tí ẹ̀yin wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà ẹni tí ahọ́n Rẹ̀ jẹ́ idà mímú.