Psalms 59:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn èmi ó kọrin ìyìn agbára rẹ; n óo kọrin sókè lówùúrọ̀, nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Nítorí ìwọ ni o ti jẹ́ odi mi ìwọ sì ni ààbò mi nígbà ìpọ́njú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn emi o kọrin agbara rẹ; nitõtọ, emi o kọrin ãnu rẹ kikan li owurọ: nitori pe iwọ li o ti nṣe àbo ati ibi-asala mi li ọjọ ipọnju mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n èmi ó kọrin agbára Rẹ, ń ó kọrin ìfẹ́ Rẹ ní òwúrọ̀; nítorí ìwọ ni ààbò mi, ibi ìsádì mi ní ìgbà ìpọ́njú.