Psalms 59:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìwọ, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, jí gìrì, kí o jẹ gbogbo orílẹ̀-èdè níyà; má da ẹnìkan kan sí ninu àwọn tí ń fi ìwà ọ̀dàlẹ̀ pète ibi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina iwọ, Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, jí lati bẹ̀ gbogbo awọn keferi wò; máṣe ṣãnu fun olurekọja buburu wọnni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA Ọlọ́run alágbára, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, dìde fún ara Rẹ kí o sì bá àwọn orílẹ̀ èdè wí; Má ṣe ṣàánú fún àwọn olùrékọjá búburú nì. Sela