Psalms 62:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Afẹ́fẹ́ lásán ni àwọn mẹ̀kúnnù; ìtànjẹ patapata sì ni àwọn ọlọ́lá; bí a bá gbé wọn lé ìwọ̀n, wọn kò lè tẹ̀wọ̀n; àpapọ̀ wọn fúyẹ́ ju afẹ́fẹ́ lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitõtọ asan li awọn ọmọ enia, eke si li awọn oloyè. Nwọn gòke ninu ìwọn, bakanna ni nwọn fẹrẹ jù asan lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní tòótọ́, asán ní àwọn ọmọ ènìyàn, èké si ni àwọn olóyè, wọn gòkè nínú ìwọ̀n bákan náà ni wọn fẹ́rẹ̀ jù asán lọ lápapọ̀ wọn jẹ èémí.