Psalms 63:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ọba yóo máa yọ̀ ninu Ọlọrun; gbogbo àwọn tí ń fi orúkọ OLUWA búra yóo máa fògo fún un; ṣugbọn a ó pa àwọn òpùrọ́ lẹ́nu mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ọba yio ma yọ̀ ninu Ọlọrun; olukuluku ẹniti o nfi i bura ni yio ṣogo: ṣugbọn awọn ti nṣeke li a o pa li ẹnu mọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ọba yóò yọ̀ nínú Ọlọ́run ẹni tí o fi orúkọ Ọlọ́run búra yóò sògo ṣùgbọ́n ẹnu àwọn òpùrọ́ la ó pa mọ́.