Psalms 66:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó sọ òkun di ìyàngbẹ ilẹ̀, àwọn eniyan fi ẹsẹ̀ rìn kọjá láàrin odò. Inú wa dùn níbẹ̀ nítorí ohun tí ó ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O sọ okun di ilẹ gbigbẹ: nwọn fi ẹsẹ là odò já: nibẹ li awa gbe yọ̀ ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
O yí òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ, wọ́n fi ẹsẹ̀ rìn inú omi kọjá, níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú Rẹ.