Psalms 69:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ní tèmi, OLUWA, ìwọ ni mò ń gbadura sí ní àkókò tí ó bá yẹ, Ọlọrun, ninu ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ninu agbára ìgbàlà rẹ, Ọlọrun dá mi lóhùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, iwọ li emi ngbadura mi si, Oluwa, ni igba itẹwọgba: Ọlọrun, ninu ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ da mi lohùn, ninu otitọ igbala rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni ìwọ ni èmi n gbàdúrà mi sí OLÚWA, ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi Rẹ, dá mí lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà Rẹ tí ó dájú.