Psalms 75:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ife kan wà ní ọwọ́ OLUWA, Ibinu Oluwa ló kún inú rẹ̀, ó ń ru bí ọtí àní bí ọtí tí a ti lú, yóo ṣẹ́ ninu rẹ̀; gbogbo àwọn eniyan burúkú ilẹ̀ ayé ni yóo sì mu ún, wọn óo mu ún tán patapata tòun ti gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe li ọwọ Oluwa li ago kan wà, ọti-waini na si pọ́n: o kún fun àdalu: o si dà jade ninu rẹ̀; ṣugbọn gèdẹgẹdẹ rẹ̀, gbogbo awọn enia buburu aiye ni yio fun u li afun-mu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọwọ́ OLÚWA ni ago kan wà, ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú, ó fún ọtí àdàlú tí a pòpọ̀ mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde, àti búburú ayé gbogbo mú u sílẹ̀ pátapáta.