Psalms 79:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà, àwa eniyan rẹ, àní, àwa agbo aguntan pápá rẹ, yóo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ títí lae; a óo sì máa sọ̀rọ̀ ìyìn rẹ láti ìran dé ìran.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃li awa enia rẹ ati agutan papa rẹ, yio ma fi ọpẹ fun ọ lailai, awa o ma fi iyìn rẹ hàn lati irandiran.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà àwa ènìyàn Rẹ, àgùntàn pápá Rẹ, yóò fi ọpẹ́ fún ọ títí láé; láti ìran dé ìran ni àwa ó fi ìyìn Rẹ hàn.