Psalms 84:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé ọjọ́ kan péré ninu àgbàlá rẹ, ṣe anfaani ju ẹgbẹrun ọjọ́ níbòmíràn lọ. Ó wù mí kí n jẹ́ aṣọ́nà ninu ilé Ọlọrun mi ju pé kí n máa gbé inú àgọ́ àwọn eniyan burúkú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori pe ọjọ kan ninu agbala rẹ sanju ẹgbẹrun ọjọ lọ. Mo fẹ ki nkuku ma ṣe adena ni ile Ọlọrun mi, jù lati ma gbe agọ ìwa-buburu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin Rẹ ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ lọ; èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run mi ju láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú.