Psalms 84:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ pàápàá a máa kọ́ ilé, àwọn alápàáǹdẹ̀dẹ̀ a sì máa tẹ́ ìtẹ́ níbi tí wọ́n ń pa ọmọ sí, lẹ́bàá pẹpẹ rẹ, àní lẹ́bàá pẹpẹ rẹ, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ọba mi, ati Ọlọrun mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitõtọ, ologoṣẹ ri ile, ati alapandẹdẹ tẹ́ itẹ fun ara rẹ̀, nibiti yio gbe ma pa awọn ọmọ rẹ̀ mọ́ si, ani ni pẹpẹ rẹ wọnni, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọba mi ati Ọlọrun mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítòotọ́ ologóṣẹ ri ilé, ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara r, níbi tí yóò máa pá ọmọ Rẹ̀ mọ́ sí: ibùgbé ní tòsí pẹpẹ Rẹ, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.