Psalms 85:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jẹ́ kí n gbọ́ ohun tí Ọlọrun, OLUWA yóo wí, nítorí pé ọ̀rọ̀ alaafia ni yóo sọ fún àwọn eniyan rẹ̀, àní, àwọn olùfọkànsìn rẹ̀, ṣugbọn kí wọn má yipada sí ìwà òmùgọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o gbọ́ bi Ọlọrun Oluwa yio ti wi: nitoriti yio sọ alafia si awọn enia rẹ̀, ati si awọn enia mimọ́ rẹ̀: ṣugbọn ki nwọn ki o má tun pada si were.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi ó gbọ́ ohun tí OLÚWA Ọlọ́run yóò wí; ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn Rẹ̀, àní ẹni mímọ́ Rẹ̀: Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmòye.