Psalms 88:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N kò yàtọ̀ sí ẹni tí a pa tì sí apá kan láàrin àwọn òkú, mo dàbí ẹni tí a pa, tí ó sùn ninu ibojì, bí àwọn tí ìwọ kò ranti mọ́, nítorí pé wọ́n ti kúrò lábẹ́ ìtọ́jú rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti a kọ̀ silẹ lãrin awọn okú, bi awọn ẹni pipa ti o dubulẹ ni isa-okú, ẹniti iwọ kò ranti mọ́: a si ke wọn kuro nipa ọwọ rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkú bí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú, ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́, ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú.