Psalms 95:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Fún ogoji ọdún gbáko ni ọ̀rọ̀ wọn fi sú mi, tí mo sọ pé, “Ọkàn àwọn eniyan wọnyi ti yapa, wọn kò sì bìkítà fún ìlànà mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ogoji-ọdun tọ̀tọ ni inu mi fi bajẹ si iran na, mo ni, Enia ti o ṣina li aiya ni nwọn, nwọn kò si mọ̀ ọ̀na mi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún ogójì ọdún ni èmi fi bínú sí ìran náà; mo wí pé, “Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ọkàn wọn sáko lọ wọn kò sì mọ ọ̀nà mi”.