Revelation 10:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ààrá meje yìí ń sán, mo fẹ́ máa kọ ohun tí wọn ń sọ sílẹ̀, ṣugbọn mo gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run, tí ó sọ pé, “Àṣírí ni ohun tí àwọn ààrá meje yìí ń sọ, má kọ wọ́n sílẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awọn ãrá meje na fọhun, mo mura ati kọwe: mo si gbọ́ ohùn lati ọrun wá nwi fun mi pe, Fi èdidi dí ohun ti awọn ãrá meje na sọ, má si ṣe kọ wọn silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn àrá méje fọhùn, mo múra àti kọ̀wé: mo sì gbọ ohùn láti ọ̀run wá ń wí fún pé, “Fi èdìdì di ohun tí àwọn àrá méje náà sọ, má sì ṣe kọ wọ́n sílẹ̀.”