Revelation 11:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Má wulẹ̀ wọn àgbàlá Tẹmpili tí ó wà lóde, nítorí a ti fi fún àwọn alaigbagbọ. Wọn yóo gba ìlú mímọ́ fún oṣù mejilelogoji.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si fi agbala ti mbẹ lode tẹmpili silẹ, má si ṣe wọ̀n ọ; nitoriti a fi i fun awọn Keferi: ilu mimọ́ na li nwọn o si tẹ̀ mọlẹ li oṣu mejilelogoji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sì fi àgbàlá tí ń bẹ lóde tẹ́ḿpìlì sílẹ̀, má si ṣe wọ̀n ọ́n; nítorí tí a fi fún àwọn aláìkọlà: ìlú mímọ́ náà ni wọn ó sì tẹ̀ mọ́lẹ̀ ní oṣù méjì lé lógójì.