Revelation 12:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Obinrin yìí bí ọmọkunrin, tí yóo jọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè pẹlu ọ̀pá irin. A bá já ọmọ náà gbà lọ sọ́dọ̀ Ọlọrun, níwájú ìtẹ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si bí ọmọkunrin kan ti yio fi ọpá irin ṣe akoso gbogbo awọn orilẹ-ède: a si gbà ọmọ rẹ̀ lọ soke si ọdọ Ọlọrun, ati si ori itẹ́ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì bi ọmọkùnrin kan tí yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè: a sì gba ọmọ rẹ̀ lọ sókè sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àti sí orí ìtẹ́ rẹ̀.