Revelation 12:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n lé Ẹranko Ewèlè náà jáde–ejò àtijọ́ nì tí à ń pè ní Èṣù, tabi Satani tí ó ń tan àwọn tí ó ń gbé inú ayé jẹ. Wọ́n lé e jáde lọ sinu ayé, ati òun ati àwọn angẹli rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si lé dragoni nla na jade, ejò lailai nì, ti a npè ni Èṣu, ati Satani, ti ntàn gbogbo aiye jẹ, a si lé e jù si ilẹ aiye, a si le awọn angẹli rẹ̀ jade pẹlu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A sì lé dírágónì ńlá náà jáde, ejò láéláé ni, tí a ń pè ni Èṣù, àti Sàtanì, tí ń tan gbogbo ayé jẹ: a sì lé e jù sí ilẹ̀ ayé, a sì lé àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ jáde pẹ̀lú rẹ̀.