Revelation 13:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó fi iṣẹ́ abàmì tí a fi fún un láti ṣe níwájú ẹranko náà tan àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé jẹ. Ó sọ fún wọn pé kí wọ́n yá ère ẹranko tí a ti fi idà ṣá lọ́gbẹ́ tí ó tún yè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ntàn awọn ti ngbe ori ilẹ aiye jẹ nipa awọn ohun iyanu ti a fi fun u lati ṣe niwaju ẹranko na; o nwi fun awọn ti ngbe ori ilẹ aiye lati ya aworan fun ẹranko na ti o ti gbà ọgbẹ idà, ti o si yè.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ń tán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé jẹ nípa àwọn ohun ìyanu tí a fí fún un láti ṣe níwájú ẹranko náà; ó ń wí fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé láti yá àwòrán fún ẹranko náà; ó ń wí fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé láti yá àwòrán fún ẹranko náà tí o tí gbá ọgbẹ́ idà, tí ó sì yè.