Revelation 13:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ohun tí ó gba ọgbọ́n nìyí. Ẹni tí ó bá ní òye ni ó lè mọ ìtumọ̀ àmì orúkọ ẹranko náà, nítorí pé bí orúkọ eniyan kan gan-an ni àmì yìí rí. Ìtumọ̀ iye àmì náà ni ọtalelẹgbẹta, ó lé mẹfa (666).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nihin ni ọgbọ́n gbé wà. Ẹniti o ba ni oye, ki o ṣiro iye ti mbẹ lara ẹranko na: nitori iye enia ni; iye rẹ̀ na si jẹ ọ̀talelẹgbẹta o le mẹfa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Niyìn ni ọgbọ́n gbé wà. Ẹni tí o bá ní òye, kí o ka nọ́ḿbà tí ń bẹ̀ lára ẹranko náà: nítorí pé nọ́ḿbà ènìyàn ni, nọ́ḿbà rẹ̀ náà sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta ọgọ́ta ẹẹ́fà. (666).