Revelation 13:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n ń júbà Ẹranko Ewèlè náà nítorí pé ó fi àṣẹ fún ẹranko yìí. Wọ́n sì ń júbà ẹranko náà, wọ́n ń sọ pé, “Ta ni ó dàbí ẹranko yìí? Ta ni ó tó bá a jà?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si foribalẹ fun dragoni na nitori o ti fun ẹranko na ni ọla: nwọn si foribalẹ fun ẹranko na, wipe, Tali o dabi ẹranko yi? tali o si le ba a jagun?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún dírágónì náà, nítorí tí o fún ẹranko náà ní àṣẹ, wọn sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, wí pé, “Ta ni o dàbí ẹranko yìí? Ta ni ó sì lè bá a jagun?”