Revelation 13:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó bá ya ẹnu, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ó ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí orúkọ Ọlọrun ati sí àgọ́ rẹ̀, ati sí àwọn tí wọ́n ń gbé ọ̀run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si yà ẹnu rẹ̀ ni isọrọ̀-odi si Ọlọrun, lati sọ ọrọ-odi si orukọ rẹ̀, ati si agọ́ rẹ̀, ati si awọn ti ngbe ọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ya ẹnu rẹ̀ ni ọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, láti sọ ọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ rẹ̀, àti sí àgọ́ rẹ̀, àti sí àwọn tí ń gbé ọ̀run.