Revelation 14:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run bí ìró ọpọlọpọ omi ati bí ìgbà tí ààrá líle bá ń sán. Ohùn tí mo gbọ́ ni ti àwọn oníhapu tí wọn ń lu hapu wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si gbọ́ ohùn kan lati ọrun wá, bi ariwo omi pupọ̀, ati bi sisán ãrá nla: mo si gbọ́ awọn aludùru, nwọn nlù dùru wọn:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá, bí aríwo omi púpọ̀, àti bí sísán àrá ńlá: mo sì gbọ́ àwọn oníháàpù, ń lù haàpù wọn.