Revelation 14:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn odi ìlú ni ìfúntí náà wà. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tẹ èso ninu rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí yọ jáde láti inú ìfúntí náà. Jíjìn rẹ̀ mu ẹṣin dé ọrùn, ó sì gba ilẹ̀ lọ ní nǹkan bí igba ibùsọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si tẹ̀ ifúnti na lẹhin odi ilu na, ẹ̀jẹ si ti inu ifúnti na jade, ani ti o tó okùn ijanu ẹṣin jinna to ẹgbẹjọ furlongi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A sì tẹ ìfúntí náà lẹ́yìn òde ilú náà, ẹ̀jẹ̀ sì ti inú ìfúntí náà jáde, ó sì ga sókè dé okùn ìjánu ẹṣin, èyí tí ìnàsílẹ̀ rẹ to ẹ̀gbẹjọ̀ ibùsọ̀.