Revelation 14:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ń kọrin titun kan níwájú ìtẹ́ náà ati níwájú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun. Kò sí ẹni tí ó lè mọ orin náà àfi àwọn ọ̀kẹ́ meje ó lé ẹgbaaji (144,000) eniyan tí a ti rà pada ninu ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si nkọ bi ẹnipe orin titun niwaju itẹ́ nì, ati niwaju awọn ẹda alãye mẹrin nì, ati awọn àgba nì: ko si si ẹniti o le kọ́ orin na, bikoṣe awọn ọkẹ́ meje o le ẹgbaji enia, ti a ti rà pada lati inu aiye wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì ń kọ bí ẹni pé orin túntún níwájú ìtẹ́ náà, àti àwọn àgbà náà: kò sì sí ẹni tí o lè kọ orin náà, bí kò ṣe àwọn òkè méje o lé ẹgbàájì ènìyàn, tí a tí rà padà láti inú ayé wá.